Henrietta Ogan is a Nigerian Business administrator and former National President of Ahmadu Bello University Alumni Association.
Henrietta Ogan jẹ́ alámójútó okùn òwò tí ó sì jẹ́ ààrẹ Ahmadu Bello University Alumni Association.


She was succeeded by Ahmed Tijani Mora, a Pharmacist and former Registrar and Chief Executive Officer of the Pharmacists Council of Nigeria.[1][2]
Ó fi ipò yìí sílẹ̀ fún Ahmed Tijani Mora, ogbónta onímọ̀ oògùn oyìnbó tí ó jẹ́ alákóso Pharmacists Council of Nigeria.[1][2]

Kola Oyewo (born March 26, 1946) is a Nigerian veteran actor, dramatist and scholar.[1]
'''Kola Oyewo''' (bìi 26 Oṣù kẹta 1946) jẹ́ òṣèré àti olùkọ́ ọmọ orìlé èdè Nàìjírìà

He was born on 27 March 1946 at Oba Ile, a town in Osun State southwestern Nigeria.[2]
A bìi ní 26 Oṣù kẹta 1946 ní ìlú Ọ̀bà ilé ti ìlú Ọ̀ṣun gúúsù-wọ̀orùn Nàìjírìà.

Education
Ètò ẹ̀kọ́

He attended Obafemi Awolowo University where he obtained a certificate in dramatic arts, a certificate in Yoruba oral literature before he later received a Bachelor of Arts (B.A.) degree in Theatre art from the same university in 1995.[3] He proceeded to the University of Ibadan where he received a Master of Arts (M.A.) and doctorate degree (Ph.D) in drama.[4]
Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Yunifásitì níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí nínu ìmo eré ìtàgé kí ó tó gba oyè kínín (B. A) nínu ìmọ tíátà ní Yunifásitì kan náà ní ọduń 1995. Ó tẹ̀síwájú nínu ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Yunifásitì ti ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti gba oyè kejì (M. A) àti ìkẹta (Ph. D) ní ìmọ eré ìtàgé.

He began acting as a professional in 1964 after he joined the "Oyin Adejobi theatre group" and the first role he played was Adejare in Orogun Adedigba which was Oyin Adejobi’s autobiography.[5] After he spent 9 years with Oyin Adejobi, he joined the University of Ife theatre, where he worked with the late veteran dramatist and scholar, chief Ola Rotimi.[6] Kola Oyewo was known for the role he played as "Odewale" in The Gods Are Not To Blame, a drama scripted by Ola Rotimi.[7]
Ipa tí ó kọ́kọ́ kó ni Adéjàre nínú eré Orogún Adédigba, èyí tí ó jẹ́ ìgbésí ayé [[Oyin Adéjọbí]].[5] Lẹ́yìn tí ó lo ọdún mẹ́ẹ́san pẹ̀lú Oyin Adéjọbí, ó darapọ̀ mọ́ egbé tíátà Yunifásitì ilé ifẹ̀ níbi tí ó tí bá olóyè [[Olá Rótìmí]], tí ó jẹ́ òṣèré àti olùkọ́ ṣisẹ́. Wọ́n mọ Kola Oyewo sí Ọdẹ́ wálé, ipa tí ó kó nínu ''The Gods Are not to Blame'', eré tí Olá Rótìmí kọ. Ní odún 1996, ó darapọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Yunifásitì bí olúkọ́, ó sì dí àgbà olùkọ́ kí ó tó fẹ̀hìntí ní Oṣù kesań 2011.[8] Lẹ́yìn tí ó fẹ̀hìntì, ó darapọ̀ mọ́ Yunifásítì Reedemers, níbi tí ó ti jẹ́ olórí olùkó ẹ̀ka eré ṣíṣe

Filmography
Àwọn eré

References
Ìtọ́kasí

Pertussis vaccine is a vaccine that protects against whooping cough.[1] There are two main types: whole-cell vaccines and acellular vaccines.[1] The whole-cell vaccine is about 78% effective while the acellular vaccine is 71–85% effective.[1][2] The effectiveness of the vaccines appears to decrease by between 2 and 10% per year with a more rapid decrease with the acellular vaccines.
Àjẹsára ikọ́ọfe jẹ̀ àjẹsára tí ń dáàbò bo ni lọ́wọ́ ikọ́ọfe.[1] Àwọn oríṣi méjì pàtakì ni ó wà: àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì àti àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì.[1] Àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì náà ní ìwọ̀n agbára àti ṣiṣẹ́ tó tó 78% nígbàti àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì ní ìwọ̀n agbára àti ṣiṣẹ́ tó tó 71–85%.[1][2] Agbára àti ṣiṣẹ́ àwọn àjẹsára náà a má a dàbí èyí tí ó dín kù pẹ̀lú ìwọ̀n 2 sí 10% lọ́dún, pẹ̀lú díndínkù tó pọ̀ jùlọ nínú àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì.

Vaccinating during pregnancy may protect the baby.[1] The vaccine is estimated to have saved over half a million lives in 2002.[3]
Fífún ni ní àjẹsára nígbàtí ènìyàn bá ní oyún lè dáàbò bo ọmọ inú oyún náà.[1] A ṣe ìṣirò pé àjẹsára náà ti dáàbò bo iye ẹ̀mí tó ju ìdajì mílíọ̀nù lọ ní ọdún 2002.[3]

The World Health Organization and Center for Disease Control and Prevention recommend all children be vaccinated for pertussis and that it be included in routine vaccinations.[1][4] This includes for people who have HIV/AIDS.
Àjọ Ìlere Àgbáyé àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn gba ni nímọ̀ràn pé kí a fún gbogbo ọmọdé ní àjẹsára ìkọ́ọfe, àti pé kí a fikún àwọn àjẹsára tí à ngbà lóòrèkóòrè.[1][4] Èyí sì kan àwọn tó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS pàápàá.

Three doses starting at six weeks of age are typically recommended in young children.
Ìwọ̀n egbògi mẹ́ẹ̀ta tí a bẹ̀rẹ̀ lọ́gán tí ọmọ bá ti pé ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ̀fà ni a má a ń sábà dámọ̀ràn fún àwọn ọmọdé kékèké.

Additional doses may be given to older children and adults.
A lè fún àwọn ọmọ tó ti dàgbà díẹ̀ síi àti àwọn àgbàlagbà ní àfikún ìwọ̀n egbògi.

The vaccine is only available in combination with other vaccines.[1]
Àjẹsára náà wà gẹ́gẹ́ bí àdàlù pẹ̀lú àwọn àjẹsára mìíràn nìkan.[1]

The acellular vaccines are more commonly used in the developed world due to less side effects.
Àwọn àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì ni a má a ń sábà lò ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ìlọsíwájú nítorí àtúnbọ̀tán rẹ̀ tí kò ní ipá púpọ̀.

Between 10 and 50% of people given the whole-cell vaccines develop redness at the injection site and fever.
Ibi ojú abẹ́rẹ́ lára iye àwọn ènìyàn tó tó 10 sí 50% tí a fún ní àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì a má a pupa yòò, wọn a sì má a ní ibà.

Febrile seizures and long periods of crying occur in less than one percent.
Gìrì àti igbe-kíké fún ìgbà pípẹ́ a má a wáyé lára iye àwọn ènìyàn tó kéré sí ìwọ̀n kan nínú ọgọ́ọ̀rún.

With the acellular vaccines a brief period of non serious swelling of the arm may occur.
Pẹ̀lú àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì, apá-wíwú tí kò ni ni lára rárá lè wáyé fún àkókò díẹ̀.

Side effects with both types of vaccines, but especially the whole-cell vaccine, are less the younger the child.
Àtúnbọ̀tán pẹ̀lú àwọn oríṣi àjẹsára náà méjèèjì, pàápàá jùlọ pẹ̀lú àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì, a má a kéré síwájú síi bí ọjọ́-orí ọmọ bá ti kéré sí.

The whole-cell vaccines should not be used after six years of age.
A kò gbọdọ̀ lo àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì fún ọmọ tí ọjọ́-orí rẹ̀ bá ti kọjá ọdún mẹ́ẹ́fà.

Serious long term neurological problems are not associated with either type.[1]
Kò sí ìṣòro ọlọ́jọ́-pípẹ́ tó jẹ mọ́ àìsàn nínú iṣan ara pẹ̀lú èyíkéèyí nínú àwọn àjẹsára méjèèjì.[1]

The pertussis vaccine was developed in 1926.[5] It is on the World Health Organization's List of Essential Medicines, the most important medication needed in a basic health system.[6] A version that also includes tetanus, diphtheria, polio, and Hib vaccine costs 15.41 USD per dose as of 2014.[7]
A ṣe àgbéjáde àjẹsára ikọ́ọfe ní ọdún 1926.[5] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[6] Iye owó ẹ̀yà rẹ̀ kan tó tún ní àwọn àjẹsára àwàlù eyín, ikọ́ gbẹ̀fun gbẹ̀fun, àrùn rọpárọsẹ̀, àti ti ọ̀fìnkì oríṣi b nínú jẹ́ 15.41 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[7]

Haemophilus influenzae type B vaccine is a vaccine used to prevent Haemophilus influenzae type b (Hib) infection.[1] In countries that include it as a routine vaccine, rates of severe Hib infections have decreased more than 90%.
Àjẹsára Ọ̀fìnkì oríṣi B tí kòkòrò àrùn Haemophilus ń fà jẹ́ àjẹsára tí ń lò láti dènà àkóràn Ọ̀fìnkì oríṣi B tí kòkòrò àrùn Haemophilus ń fa (Hib).[1] Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti kàá kún ara àjẹsára tí à ń lò lóòrèkóòrè, iye àkóràn àrùn Hib tó ní ipá ti dín kù pẹ̀lú ìwọ̀n tó ju 90% lọ.

It has therefore resulted in a decrease in the rate of meningitis, pneumonia, and epiglottitis.[1]
Èyí sì ti mú kí àwọn àrùn bíi dídáranjẹ̀ awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó bo ọpọlọ àti ọ̀pá-ẹ̀yìn (meningitis), dídáranjẹ̀ ẹ̀dọ̀fóró (pneumonia), àti dídáranjẹ̀ bèlú-bèlú (epiglottitis) dín kù lọ́pọ̀lọpọ̀.[1]

It is recommended by both the World Health Organization and Centers for Disease Control and Prevention.[2][1] Two or three doses are should be given before six months of age.
Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn fọwọ́sí ìmúlò rẹ̀.[2][1] Ìwọ̀n egbògi náà méjì tàbí mẹ́ẹ̀ta ni a gbọ́dọ̀ fún ènìyàn kí ó tó pé ọmọ oṣù mẹ́ẹ́fà.

The first dose is recommended around six weeks of age with four weeks between doses.
Ìwọ̀n egbògi àkọ́kọ́ ni a gba ni nímọ̀ràn láti gbà bí ènìyàn bá ti ń pé ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ́fà, èkejì sì gbọdọ̀ wáyé ní ọ̀sẹ̀ kẹẹ̀rin sí àsìkò yìí.

If only two doses are used another dose latter in life is recommended.
Bí ó bá jẹ́ ìwọ̀n àjẹsára náà méjì péré ni a fún ni, a gba ni nímọ̀ràn láti gba ìwọ̀n àjẹsára náà mìíràn lọ́jọ́ iwájú.

It is given by injection into a muscle.[1]
A má a ń gbàá gẹ́gẹ́ bí abẹ́rẹ́ tí a gún sínú ẹran-ara ẹni.[1]

Severe side effects are uncommon.
Àtúnbọ̀tán tó ní ipá kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀.

About 20 to 25% of people develop pain at the site of injection while about 2% develop a fever.
Iye àwọn ènìyàn tó tó 20 sí 25% a má a ní ìrora ní ojú ibi abẹ́rẹ́ náà, àwọn bíi 2% a sì má a ní ibà.

There is no clear association with severe allergic reactions.
A kò rí ẹ̀rí tó fihàn kedere pé àjẹsára náà ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìfèsì ara ẹni lọ́nà òdì sí ohun tí ènìyàn kòrira.

The Hib vaccine is available by itself, in combination with the diptheria/tetanus/pertussis vaccine, and in combination with the hepatitis B vaccine, among others.
Àjẹsára Hib wà gẹ́gẹ́ bí èyí tó dádúró, bí èyí tó jẹ́ àdàlù pẹ̀lú àjẹsára ikọ́ gbẹ̀fun-gbẹ̀fun/àwàlù eyín/ikọ́ọfe, àti bí èyí tó jẹ́ àdàlù pẹ̀lú àjẹsára Ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ oríṣi B, láàárín àwọn oríṣiríṣi mìíràn.

All Hib vaccines that are currently used are conjugate vaccine.[1]
Gbogbo àwọn àjẹsára Hib tí à ń lò báyìí jẹ́ àjẹsára aláàsopọ̀.[1]

An initial Hib vaccine was developed in 1977 which was replaced by a more effective formulation in the 1990s.
Àjẹsára Hib àkọ́kọ́ ni a ṣe jáde ní ọdún 1977, èyí tí a rọ́pò pẹ̀lú àgbéjáde mìíràn tí nṣiṣẹ́ dáradára jùú lọ ní àwọn ọdún 1990.

As of 2013, 184 countries include it in their routine vaccines.[1] It is on the World Health Organization's List of Essential Medicines, the most important medications needed in a basic health system.[3] The wholesale cost of a pentavalent vaccine which includes Hib was 15.40 USD per dose as of 2014.[4] In the United States it costs about 25 to 50 USD per dose.[5]
Ní ọdún 2013, orílẹ̀-èdè 184 ni wọ́n fi sí ara àwọn àjẹsára òòrèkóòrè wọn.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[3] Iye owó rẹ̀ lójú pálí fún àjẹsára tó ní ojú ibi àsopọ̀ máàrún, ọ̀kan lára èyítí ó jẹ́ Hib, jẹ́ 15.40 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[4] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ bíi 25 sí 50 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo.[5]

Influenza vaccines, also known as flu shots, are vaccines that protect against influenza.[2] A new version of the vaccine is developed twice a year as the influenza virus rapidly changes.[2] Most provide modest to high protection against influenza; however, each year this varies.[3][2] Evidence in adults over 65 years old is poor.[4][5] They decrease the number of missed days of work by a half day on average.[6] Vaccinating children may protect those around them.[2]
Àjẹsára ọ̀fìnkì, tí a tún mọ̀ sí àbẹ́rẹ́ ọ̀fìnkì, jẹ́ àjẹsára tí ń dáàbò bo ni lọ́wọ́ ọ̀fìnkì.[2] A má a ń ṣe àgbéjáde ẹ̀yà àjẹsára náà titun lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún nítorí tí kòkòrò àrùn àìlèfojúrí afàìsàn ọ̀fìnkì a má a paradà kíákíá.[2] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn a má a pèsè ààbò tó mọ níwọ̀n àti èyí tó lágbára púpọ̀ fúnni lọ́wọ́ ọ̀fìnkì; ṣùgbọ́n, èyí a má a yàtọ̀ láti ọdún dé ọdún.[3][2] Ẹ̀rí iṣẹ́ rẹ̀ lára àgbàlagbà tí ọjọ́-orí rẹ̀ ti ju ọdún 65 lọ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀.[4][5] Wọn a má a dín iye ọjọ́ tí àwọn ènìyàn kò fi níí lè lọ sí ibi-iṣẹ́ kù sí bíi ìdajì ọjọ́ bí a bá wòó lápapọ̀.[6] Fífún àwọn ọmọdé ní àjẹsára lè dáàbò bo àwọn ẹlòmíràn tó wà ní àyíká wọn.[2]

Both the World Health Organization and Centers for Disease Control and Prevention recommends nearly all people over the age of 6 months get the vaccine yearly.[2][7] This is especially true for pregnant women, children between six months and five years of age, those with other health problems, Native Americans, and those who work in healthcare.[2][1]
Àti Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn ni ó gba ni níyànjú pé kí gbogbo ẹnití ọjọ́-orí rẹ̀ bá ti ju oṣù 6 lọ má a gba àjẹsára náà lọ́dọọdún.[2][7] Èyí ṣe pàtàkì púpọ̀ pàápàá jùlọ fún àwọn obìrin tó ní oyún, àwọn ọmọdé tí ọjọ́-orí wọn jẹ́ bí oṣù mẹ́fá sí ọdún máàrún, àwọn tó ní ìṣòrò yòówù nípa ìlera wọn, Àwọn Ọmọ Abínibí Amẹ́ríkà, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlera.[2][1]

The vaccines are generally safe.
Àwọn àjẹsára náà kò léwu láti lò.

In children fever occurs in between 5 to 10%, as may muscle pains, a feeling tired.
Ní àárín àwọn ọmọdé ibà a má a wáyé láàárín iye àwọn ọmọ tó tó ìwọ̀n 5 sí 10 nínú ọgọ́ọ̀rún, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrora nínú ẹran-ara, àti àárẹ̀ náà lè wáyé.

Certain years, among older people, the vaccine causes Guillain Barre syndrome in about one per million doses.
Ní àwọn ọdún mìíràn, láàárín àwọn àgbàlagbà, àjẹsára náà a má a fa àìsàn tí à n pè ní Guillain Barre syndrome ní ìwọ̀n egbògi náà kan nínú mílíọ̀nù kan.

It should not be given to those with severe allergies to eggs or previous versions of the vaccine.
A kò gbọdọ̀ lòó fún àwọn tó ní ìfèsì ara ẹni lọ́nà tó burú púpọ̀ sí ẹyin tàbí sí oríṣi àjẹsára náà àtijọ́.

They come in both inactive and weakened viral forms.
Wọn a má a wá bíi oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti pa ṣe, àti bíi oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn náà ti a ti sọ di aláìlágbára ṣe.

The inactive version should be used those who are pregnant.
Oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn tí a ti pa ṣe ni a gbọ́dọ̀ lò fún àwọn aboyún.

They come in forms that are either injected into a muscle or sprayed into the nose.[2]
Wọn a má a wá bíi oríṣi tí à ń gún bí abẹ́rẹ́ sínú ẹran-ara ẹni tàbí bíi oríṣi tí à ń fún sínú imú ẹni.[2]

Vaccination against influenza began in the 1930s with large scale availability in the United States beginning in 1945.[8][9] It is on the World Health Organization's List of Essential Medicines, the most important medication recommended for a basic health system.[10] The wholesale price is about 5.25 USD per dose as of 2014.[11] In the United States it costs less than 25 USD.[12]
Gbígba àjẹsára fún ààbò lọ́wọ́ ọ̀fìnkì bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, nígbàtí wíwà fún lílò gbogbogbò ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1945.[8][9] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[10] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 5.25 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[11] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ kò tó 25 USD.[12]

Mumps vaccines safely prevent mumps. When given to a majority they decrease complications at the population level.[1] Effectiveness when 90% of a population is vaccinated is estimated at 85%.[2] Two doses are required for long term prevention.
Àjẹsára ṣegede a má a dènà àrùn ṣegede láìséwu. Bí a bá lòó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọn a má a dín ìnira tíì bá wáyé nípasẹ̀ àrùn náà kù láàárín àwùjọ.[1] Ipá rẹ̀ bí a bá lòó fún ìwọ̀n ènìyàn tó tó 90% láàárín àwùjọ kan ni a ṣírò sí bíi 85%.[2] Ìwọ̀n egbògi náà méjì ni a nílò láti dènà àrùn náà fún ìgbà pípẹ́.

The initial dose is recommended between the age of 12 and 18 months of age.
Ìwọ̀n egbògi àkọ́kọ́ ni a dámọ̀ràn fún lílò láàárín ìgbà tí ènìyàn bá ti pé ọmọ oṣù 12 sí 18.

The second dose is than typically given between two years and six years of age.[1] Usage after exposure in those not already immune may be useful.[3]
Ìwọ̀n egbògi kejì ni a ó ò fúnni láàárín ìgbà tí ènìyàn bá di ọmọ ọdún méjì sí ọmọ ọdún mẹ́ẹ́fà.[1] Lílò rẹ̀ lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti wà ní sàkání ibití àrùn náà ti wáyé, fún àwọn tí kò tíì ní agbára àti kojú àrùn tẹ́lẹ̀ rí, jẹ́ ohun tí yóò wúlò púpọ̀.[3]

The mumps vaccine is very safe and side effects are generally mild.[1][3] It may cause mild pain and swelling at the site of injection and mild fever.
Àjẹsára ṣegede jẹ́ èyítí kò léwu láti lò, àwọn àtúnbọ̀tán rẹ̀ kìí sì ní ipá rárá.[1][3] Ó lè fa ìrora díẹ̀ pẹ̀lú wíwú ojú ibi abẹ́rẹ́, àti ibà díẹ̀.